Breaking News

2027: Ẹgbẹ oselu PDP kede ibi ti oludije funpo aarẹ yoo ti wa

0 0



By Olalere Tolulope

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti kede pe iha Guusu orileede yii (South) ni yoo fa oludije ti wọn yoo lo lati kojuu ẹgbẹ All Progressives Congress ninu idibo apapọ ọdun 2027 kalẹ.

Nibi ipade apapọ awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ, ikejilelọgọrun iru ẹ, to waye laipẹ yii ni wọn ti sọ pe awọn gbe igbesẹ yii lẹyin ti awọn ṣayẹwo abọ igbimọ kan ti gomina ipinlẹ Bayelsa, Douye Diri, jẹ alaga rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ṣe ni ẹgbẹ PDP juwọ silẹ lọdun 2023, wọn ni oludije funpo aarẹ le wa lati ibikibi lorileede yii, nipasẹ eyi si ni igbakeji aarẹ ilẹ yii nigba kan ri, Alhaji Atiku Abubakar, fi di oludije wọn.

Igbesẹ yii da wahala pupọ silẹ nigba naa, awọn adari ẹgbẹ kan niha Guusu, eleyii ti gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, to ti di Minisita fun olu ilu ilẹ wa Abuja bayii, Nyesom Wike, ko sodi, faraya, wọn ni iyanjẹ ni bi wọn ko ṣe gbe ipo naa lọ si Guusu orileede yii.

Lopin rogbodiyan yii, ẹgbẹ PDP fidi rẹmi, ipo aarẹ si bọ si ọwọ Aare Bọla Ahmed Tinubu latinu ẹgbẹ All Progressives Congress.

Amọ nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade wọn, akọwe ipolongo ẹgbẹ PDP lorileede yii, Debọ Ologunagba, sọ pe ẹgbẹ ti fọwọ si i bayii pe ki awọn eeyan Guusu fa oludije funpo aarẹ kalẹ.

O ni gbogbo ipo to jẹ ti apapọ ẹgbẹ, eyi ti awọn eeyan apa Ariwa di mu lọwọlọwọ ṣi wa bẹẹ, bẹẹ ni awọn ipo to wa ni Guusu lọwọlọwọ naa wa bẹẹ.

Lara ohun ti wọn tun fẹnu ko le lori nibi ipade naa, gẹgẹ bi Ologunagba ṣe sọ ni pe, niwọn igba ti wọn ti jọwọ ipo alaga apapọ ẹgbẹ fun awọn eeyan Ariwa, ki oludije wa lati Guusu.

Ni bayii, o ni o ku si awọn eeyan Guusu orileede yii lọwọ lati mọ bi wọn ṣe fẹẹ ṣatupalẹ ọrọ naa lati le mọ ibi ti oludije yoo ti wa gan an.

Nibẹ ni wọn tun ti fontẹ lu Umar Damagum gẹgẹ bii alaga apapọ ẹgbẹ PDP lorileede yii, wọn ni ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ ọdun yii ni iṣẹ rẹ bẹrẹ gẹgẹ bii alaga gan-an-gan lẹyin to ti ṣe adele fungba diẹ.

Ẹgbẹ PDP bu ẹnu atẹ lu bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n fi tipatipa ko awọn ọmọ ẹgbẹ wọn mọra nipasẹ idunkoko-mọni, fifi owo tan ni ati dida wahala silẹ kaakiri, iru eyi to ṣẹlẹ lawọn agbegbe ti atundi ibo ti waye kọja.

Wọn ni awọn ologun ni ẹgbẹ APC fi dẹruba awọn oludibo nipinlẹ Kaduna ati Taraba pẹlu Zamfara, ti awọn ẹṣọ alaabo si ju awọn oludibo lọ lẹkun-idibo Kaura.

Gbogbo eleyii, gẹgẹ bi ẹgbẹ PDP ṣe wi, jẹ erongba ẹgbẹ APC lati sọ orileede yii di ti ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo, eyi to si lewu pupọ fun ijọba tiwantiwa ati ibagbepọ iṣọkan ni Naijiria.

Ẹgbẹ naa fi da awọn ọmọ orileede yii loju pe atunto nla ti bẹrẹ bayii lati le wa ni imurasilẹ fun idibo apapọ ọdun 2027.

Osun Spring

Click to Join Our WhatsApp Group

Click to Join Our WhatsApp Channel

Happy
Happy
0 %
Sad
Sad
0 %
Excited
Excited
0 %
Sleepy
Sleepy
0 %
Angry
Angry
0 %
Surprise
Surprise
0 %

Average Rating

5 Star
0%
4 Star
0%
3 Star
0%
2 Star
0%
1 Star
0%

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *