
Nigba ti awọn Yoruba sọ pe ẹni a ro pe ko le pa’gọ, to kọle alaruru, Gomina Ademọla Nurudeen Jackson Adeleke ni wọn ni lọkan nigba naa, o fitan balẹ, o si sọ ara rẹ di manigbagbe nipinlẹ Ọṣun.
Latigba ti ẹgbọn rẹ, Sẹnetọ Isiaka Adetunji Adeleke Ṣẹrubawọn ti darapọ mọ oṣelu ni gbogbo eeyan ti mọ Ademọla Adeleke gẹgẹ bii ẹni to fẹran ijo jijo, ko si si ibi ti ẹgbọn rẹ ya si ti ko ni ba a lọ.
Ohun kan to mu ki idile wọn, iyẹn idile Adeleke niluu Ẹdẹ yatọ ni pe gbagbagba ni wọn maa n duro ti ara wọn ninu ohun rere ṣiṣe, o si jẹ idile ti gbogbo aye mọ si ẹlẹyinju aanu lati ọpọ ọdun sẹyin.
Bi Ṣẹrubawọn ṣe n ṣepolongo ibo kaakiri; yala nigba to fẹẹ di gomina ati nigba to fẹẹ ṣe Sẹnetọ, ko sibi to lọ ti ẹ ko ti nii ri Ademọla Adeleke, tayọtayọ ni yoo si fi maa fi talẹnti ti Eledua fun un han.
Lẹyin iku ẹgbọn rẹ, awọn agbaagba ẹgbẹ PDP pinnu pe inu iran Adeleke ni ki ẹni ti yoo gba ipo rẹ nile igbimọ aṣofin agba ti jade wa, bii ere, bii ere, wọn fa Ademọla Adeleke silẹ, o si fidi gbogbo awọn alatako rẹ rẹmi pooropo ninu idibo ọhun.
Lọdun un 2017, nigba ti imurasilẹ fun idibo gomina ipinlẹ Ọṣun bẹrẹ, ẹgbẹ PDP tun fa Sẹnetọ Ademọla Adeleke silẹ, ṣugbọn ohun akọkọ ti awọn alatako gbe jade nipa rẹ ni pe o kundun ijo jijo, nitori naa ko si ohun rere kankan to le ti ‘Nazareeti’ aye rẹ jade.
Wahala yii pọ to bẹẹ gẹẹ, ṣugbọn ohun kan ṣoṣo to maa n jade lẹnu Adeleke nigba naa ni pe ọmọ omiran ki i ya arara, ọmọ ti ẹya ba bi, o di dandan ko jọ ẹya.
O ni ọna kan ṣoṣo ti ohun mọ lati fi maa kan saara si Aṣẹdaa ni ijo jijo, ko si ni nnkan kan ṣe pẹlu oniruuru afojusun rere ti oun ni fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.
Lẹyin-o-rẹyin, idibo ọdun 2018 waye, ko sẹni ti ko mọ pe ọmọ Balogun jawe olubori, ṣugbọn awọn alagbara fi ọwọ-ọla gba a loju titi de kootu, iyan ọrọ yii waa di atungun, ọbẹ rẹ si di atunse.
Gbogbo awọn ololufẹ Ademọla Adeleke ko sinmi, bẹẹ ni ẹgbẹ PDP gan an sọ pe agbo to tadi mẹyin lawọn yoo fi ọrọ naa ṣe, agbara lo gbọdọ mu pada bọ.
Bo ṣe di ọdun 2021 ni igbaradi fun idibo gomina ọdun 2022 bẹrẹ, ere ni, awada ni, Ademọla Adeleke jo wọnuu sẹkiteriati ijọba lẹyin ti wọn bura fun un gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2022.
Lati ọjọ naa, bo tilẹ jẹ pe ọta ẹni ki i pa odu-ọya, ajanaku awọn iṣẹ Adeleke kọjaa mo ri nnkan firi, awọn aṣeyọri ijọba rẹ lẹkajẹka ko ṣe e gbe sabẹ orule, imọlẹ ni, gẹgẹ bii apejẹ orukọ rẹ.
Melo la fẹẹ ka ninu eyin adipele, ti’nu ọrun, ti ita, eje ni. Gẹgẹ bii gomina to nigbagbọ ninuu awọn iṣẹ akanṣe to maa n ṣe ọpakutẹlẹ fun idagbasoke agbegbe, Adeleke kọkọ mojuto awọn oju-ọna to so ilu kọọkan papọ.
Ohun ti Adeleke maa n sọ ni pe ti awọn ọna keekeke aarin ilu ba ti ṣe e rin, yoo rọrun fun awọn agbẹ nigberiko lati ko ounjẹ wọnu ilu, ti ebi ba si ti kuro ninu iṣẹ, iṣẹ ti buṣe.
Ọna onikilomita bii aadọjọ ni wọn kọkọ ṣe kaakiri ninu rẹ si ni ọna onikilomita kan aabọ ti wọn ṣe si ijọba ibilẹ kọọkan wa, ko si si ilu ti ọwọja iṣẹ oju-ọna yii ko de ni ọdun akọkọ iṣejọba Adeleke.
Lẹyin ọdun mẹrinlelogoji ti awọn eeyan ilu Ayegbaju ati Irẹsi ti n bẹ awọn ijọba to ti kọja fun ọna to duroore, Adeleke dẹrin pẹẹkẹ wọn nipa ṣiṣe ọna to so ilu mejeeji papọ, o si sọ orukọ gomina di manigbagbe niluu mejeeji.
Ọna onikilomita mẹta nijọba yii ṣe ninu ilu Irẹsi, oju-ọna Ọja Mọnde si Station Road niluu Ikirun naa ko gbẹyin. Ijọba yii tun ṣe ọna Iyana ọja Saturday si General Hospital kọja si NUD 2 si Lawyer Bọlade Road niluu Ikirun.
Niluu Ikire, ọna orita Ibadan/Ifẹ Expressway si Islamiyyah-Okiti Junction ti wọn ti pa ti lati ọdun marundinlogoji sẹyin gba atunṣe nipasẹ ijọba Ademọla Adeleke, bẹẹ ni wọn tun ọna Ẹnuwa si Oniyangi-Ita Ọṣun-Oke Atan kọja si Ẹgbẹdu-Ilode niluu Ileefẹ ṣe.
Lẹyin ọdun mọkanlelogoji, iṣejọba Adeleke tun ọju-ọna Ansarudeen Central Mosque Junction kọja si Kuti Junction ni Hospital Road niluu Iwo ṣe.
Yatọ si awọn eleyii, ijọba yii sọ oju-ọna Akoda si Ido-Ọṣun, Old Garage si Okefia si Lameco niluu Oṣogbo, Akoda si Baptist High School niluu Ẹdẹ di alabala meji, eleyii to mu un rọrun fun awọn arinrinajo lati kọja lai si idiwọ.
Afara abẹyẹfo marun nijọba yii n ṣe lọwọ kaakiri ipinlẹ Ọṣun, papanbari rẹ ni eyi to wa ni Okefia niluu Oṣogbo eleyii ti yoo di siṣi laipẹ yii.
Ijọba yii ko dẹyẹ si awọn ọna to jẹ tijọba apapọ to wa ninu ipinlẹ Ọṣun nitori igbayegbadun awọn olugbe ipinlẹ yii lo jẹ wọn logun.
Ni ti ẹka eto ilera, ileewosan alabọọde bii igba (200) nijọba yii ṣatunṣe rẹ, ti wọn si ko obitibiti oogun sibẹ fun ilera pipe awọn araalu.
Awọn to to ẹgbẹrun lọna ọgọrun ni wọn n janfaani eto ilera adojutofo lọfẹẹ, lara wọn si ni awọn oṣiṣẹfẹyinti, awọn to wa lọgba ẹwọn atawọn akanda ẹda.
Wọn ti ṣe iṣẹ-abẹ ọfẹ fun awọn araalu bii ẹgbẹrun lọna mejidinlogun kaakiri awọn ẹkun idibo mẹsan to wa nipinlẹ Ọṣun lai fi ti ẹsin, ẹya tabi ẹgbẹ oṣelu ṣe rara. Nipasẹ eyi ni gomina fi gba ẹmi-ẹyẹ gẹgẹ bii gomina to ṣiṣẹ takuntakun julọ lori eto ilera lorileede yii loṣu diẹ sẹyin.
Ni ẹka eto ẹkọ, laarin ọdun mẹta pere, ijọba yii ti da bẹbẹ kọja ero awọn eeyan. Ileewe to to ọgọrun ti wọn ti dẹnukọlẹ nijọba yii ti tun ṣe lati mu ẹkọ rọrun fawọn akẹkọọ atawọn olukọ.
Sisan owo iranwọ, Bursary, fun awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ ipinlẹ Ọṣun kaakiri awọn ile-ẹkọ giga lorileede yii mu ki awọn akẹkọọ ti wọn jẹ ogo ọjọ-ọla ni igbagbọ kikun ninu iṣejọba yii.
Ile-ẹkọ awọn olukọni to wa niluu Ileṣa di Fasiti Ileṣa, bẹẹ ni oniruuru awọn iṣẹ akanṣe ti wọn ti pa ti ni Fasiti Ọṣun di ṣiṣẹ lasiko Adeleke.
Gbogbo awọn ileewe alakọbẹrẹ ati ti girama nijọba ko awọn iwe ati irinṣẹ ikẹkọọ si bamubamu, bẹẹ ni ipese aga ati tabili ikọwe ko gbẹyin.
Inu igbadun nla lawọn olukọọ wa bayii kaakiri ileewe ijọba pẹlu bijọba ṣe n ṣe koriya fun wọn nipa sisan owo oṣu wọn loorekoore.
Ọdun mejila ṣaaju iṣejọba yii ni ara fi ni awọn oṣiṣẹfẹyinti ti wọn lo odidi ọdun marundinlogoji ninu ọjọ aye wọn fun iṣẹ labẹ ijọba Ọṣun, ṣugbọn latigba ti Adeleke ti de ni gbogbo nnkan yatọ, wọn si n gba owo iféyinti ati ajẹmọnu wọn lai si laalaa.
ohun to tun jẹ afiyesi ninu ọrọ Adeleke ni pe gbogbo iṣẹ akanṣe ti awọn gomina to ti ṣejọba sẹyin ko lanfaani lati pari lo ṣe finnifinni, idi niyẹn ti gomina ijẹta l’Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, fi sọ nibi eto kan niluu Ileṣa pe Gomina Adeleke ya oun lẹnu pupọ nitori awọn iṣẹ ti iṣejọba oun ko pari, ti ẹni ti oun gbesẹ fun si pa ti, ni gomina n ṣe.
Ibaṣepọ aarin awọn oṣiṣẹ alaabo nipinlẹ Ọṣun labẹ iṣejọba Gomina Ademọla Adeleke duro dan-in-dan-in, idi niyẹn ti ko fi si ifọkanbalẹ fun awọn ọdaran nigberiko ati ninu ilu nlanla.
Ni ti imọ-ẹrọ, iṣejọba Adeleke ri i daju pe awọn ọdọ ti wọn kọṣẹmọṣẹ ni ẹka yii lo talẹnti ati ọgbọn-inu wọn. Ṣaṣa ni ilu ti ko si lorii maapu atọnisọna ayelujara, iyẹn goggle, nipinlẹ Ọṣun.
Ni ẹka okoowo ati idaṣẹsilẹ, bi alaafia ṣe wa nipinlẹ Ọsun ti ṣokunfa bi ọpọ awọn oludokoowo ati oludaṣẹssilẹ lorileede yii ati loke-okun ṣe n fi ifẹ han bayii lati waa daṣẹ silẹ, eyi ti yoo tun pese anfaani nla fun awọn ọdọ lati ri iṣẹ ṣe lai laagun.
Laarin awọn gomina nilẹ Yoruba ati lorileede Naijiria lapapọ, Gomina Ademọla Adeleke ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin, gbogbo nnkan to le mu idagbasoke ba awọn araalu lo maa n fojoojumọ ṣe.
Ẹni to ba rin kaakiri ipinlẹ Ọṣun, pẹlu ọkan to tọ, yoo mọ pe ejo ti wọ kuro nibi tana, ko si ẹka ti imọlẹ ko tan de, gbogbo araalu ni wọn si n sọ pe oun nikan naa lo le gbe ipinlẹ yii de ebute aṣeyọri paapaa lasiko ti eto ọrọ-aje dẹnukọlẹ lorileede yii.
Aṣeyọri iṣejọba Gomina Ademọla Nurudeen Jackson Adeleke laaarin ọdun mẹta yii kọja ọrọ ẹgbẹ oṣelu, o ṣafihan ifẹ tootọ to ni lati sin awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ati ipinnu rẹ lati tubọ sọ orukọ idile to ti jade di manigbagbe si rere.
Click to Join Our WhatsApp Group
Click to Join Our WhatsApp Channel


Average Rating